
Ilé
Oreoluwa David (DNA)
Preview
Song Lyrics (Below)
Stream/Download and Enjoy!
Release DateNovember 15, 2024
Lyrics
Ìlànà ìgbésẹ̀ ènìyàn rere
wá l’áti ọ̀dọ̀ Olúwa wá
Ó sì ṣe inú dídùn sí ọ̀naa rẹ̀
Bí ó ti lẹ̀ ṣubú
A kì yíò taá nù pátá pátá
Nítorí tí Olúwa di ọwọ́ọ rẹ̀ mú
Èmí ti wà ní èwe
Báyìí
Èmí sì ti dàgbà
Síbẹ̀
Ẹ̀mi kò tíi rí kí á kọ olódodo s’ílẹ̀
Tàbí kí irú ọmọ rẹ̀ máa ṣ’agbe ónjẹ
Aláàánú ni òhun ní’gbàgbogbo
A máa yáni
Asì máa bùsi fún ni
Bí o bá yí s’ápá òtún
Tàbí apá òsì
Etí ìrẹ yíó ma gbọ́ oùn kan lẹ́yìn rẹ wípé
Ọ̀nà n’ìyí
Máa rìn nínúurẹ̀
Ariwo ọjà yín pani o o o o
F’ọ̀nà ilé hàn mío
Ràn mí lọ́wọ́
Ràn mí lọ́wọ́ kín délé
Chant
My mind; Ooooo my mind
My Soul; be still as His glorious light fills my way.
Ariwo ọjà yín pani o o o o
Ṣáà máa f’ọ̀nà hàn mío
Ràn mí l’ọ́wọ́
Ràn mí l’ọ́wọ́ kín dé ilé